PSALM 139 [YORUBA] B

14. Mo yìn ọ́, nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ati ẹni ìyanu ni ọ́; ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ! O mọ̀ mí dájú. Nígbà tí à ń ṣẹ̀dá egungun mi lọ́wọ́ ní ìkọ̀kọ̀, tí ẹlẹ́dàá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣọnà sí mi lára ní àṣírí, kò sí èyí tí ó pamọ́ fún ọ. Kí á tó dá mi tán ni o ti rí mi, o ti kọ iye ọjọ́ tí a pín fún mi sinu ìwé rẹ, kí ọjọ́ ayé mi tilẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ rárá. Ọlọrun, iyebíye ni èrò rẹ lójú mi! Wọ́n pọ̀ pupọ ní iye. Bí mo bá ní kí n kà wọ́n, wọ́n pọ̀ ju iyanrìn lọ; nígbà tí mo bá sì jí, ọ̀dọ̀ rẹ náà ni n óo wà. ⨯ Ọlọrun, ò bá jẹ́ pa àwọn eniyan burúkú, kí àwọn apànìyàn sì kúrò lọ́dọ̀ mi. Wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ nípa rẹ, àwọn ọ̀tá rẹ ń ba orúkọ rẹ jẹ́. OLUWA, mo kórìíra àwọn tí ó kórìíra rẹ; mo sì kẹ́gàn àwọn tí ń dìtẹ̀ sí ọ? Mo kórìíra wọn dé òpin; ọ̀tá ni mo kà wọ́n kún. Wádìí mi, Ọlọrun, kí o mọ ọkàn mi; yẹ̀ mí wò, kí o sì mọ èrò ọkàn mi. Wò ó bí ọ̀nà ibi kan bá wà tí mò ń tọ̀, kí o sì tọ́ mi sí ọ̀nà ayérayé.

Advertisements

Leave a Reply

Fill in your details below or click an icon to log in:

WordPress.com Logo

You are commenting using your WordPress.com account. Log Out /  Change )

Google+ photo

You are commenting using your Google+ account. Log Out /  Change )

Twitter picture

You are commenting using your Twitter account. Log Out /  Change )

Facebook photo

You are commenting using your Facebook account. Log Out /  Change )

w

Connecting to %s