ILE IDALENU TI OLORUN (GOD’S REFUSE BARN)

Ile idalenu (refuse barn) je ohun ti o se pataki ninu ile gbogbo. O je ibiti a ma nda panti ati awon ohun ti ko wulo fun wa ninu ile mosi. (Mosi gbagbo pe iwo naa ni okan).
Olorun paapaa ni ile idalenu. Ile idalenu ti olorun yi je kariaye. Mo fe ki o ronu lori titobi olorun ati bi ile idalenu re yoo ti to. O je ibi ti a yasoto fun ghogbo ohun elegbin inu aye yi, awon ohun ti ko ni iwulo ninu aye titun ti olorun yoo da ni yoo koju sinu ile idanilenu yi.
Awon wonni ti ki yoo ni iwulo ninu ile titun ti Olorun naa ni awon eniyan tio ko Olorun sile ni aye isisinyi. Olorun ti fi ipe ranse si gbogbo eniyan lati to o wa nipase omo bibi re Jesu Kristi. Ofi ife ailegbe han si eniyan nipa fifi omo bibi re kan soso rubo fun ese araye.
Gbo eda ti o ba gba ipe Olorun lati too wa nipase Jesu Kristi yoo di ajumojogun ebi tuntun olorun ninu ile re titun. Sugbon gbogbo awon ti o ko ipe Olorun ti fi han wipe awon ko nilo re. A ki yoo fi aye gba iru awon wonyi ninu ile titun Olorun.
Awon wonyi ni a o kasi ohun elegbin ti o ye fun ile idalenu tii se Orun apaadi. “Sugbon awon ti o beru ati alaigbagbo ati eni irira, ati apaniyan ati alagbere ati oso ati aborisa ati awon eke gbogbo ni yoo ni ipa tiwon ninu adagun ina ti nfi sulfuru jo: eyi ti i se iku keji” Ewo lo yan, se ile titun Olorun ni tabi ile idalenu Re?

Olorun, o da mi ni aworan ara re, o si fi omo re sile lati ku fun mi nitori ese mi. Dariji mi loni, mo pada sodo re pelu gbogbo okan mi. Saanu fun mi nitori mi o kin se ohun ti oye fun ile idalenu. Mo ni ife re, mo gba iwe ipe re ninu Kristi Jesu, mu mi lo si ile titun re. Mo fi gbogbo re sile fun o. Ose Jesu Oluwa.

Advertisements

Leave a Reply

Fill in your details below or click an icon to log in:

WordPress.com Logo

You are commenting using your WordPress.com account. Log Out /  Change )

Google+ photo

You are commenting using your Google+ account. Log Out /  Change )

Twitter picture

You are commenting using your Twitter account. Log Out /  Change )

Facebook photo

You are commenting using your Facebook account. Log Out /  Change )

w

Connecting to %s